Isa 40:12-14
Isa 40:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn? Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ? Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a?
Isa 40:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun? Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run, Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé sinu òṣùnwọ̀n? Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n? Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA, ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye, ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́, tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀, tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án?
Isa 40:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n? Ta ni ó ti mọ ọkàn OLúWA, tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ta ni OLúWA ké sí kí ó là á lọ́yẹ àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́? Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?