Isa 40:30-31
Isa 40:30-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ani ãrẹ̀ yio mu awọn ọdọmọde, yio si rẹ̀ wọn, ati awọn ọdọmọkunrin yio tilẹ ṣubu patapata: Ṣugbọn awọn ti o ba duro de Oluwa yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyẹ́ gùn oke bi idì; nwọn o sare, kì yio si rẹ̀ wọn; nwọn o rìn, ãrẹ̀ kì yio si mu wọn.
Isa 40:30-31 Yoruba Bible (YCE)
Yóo rẹ àwọn ọ̀dọ́ pàápàá, agara óo sì dá wọn, àwọn ọdọmọkunrin yóo tilẹ̀ ṣubú lulẹ̀ patapata. Ṣugbọn àwọn tí ó bá dúró de OLUWA yóo máa gba agbára kún agbára. Wọn óo máa fi ìyẹ́ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì. Wọn óo máa sáré, agara kò ní dá wọn; wọn óo máa rìn, kò sì ní rẹ̀ wọ́n.
Isa 40:30-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú; ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLúWA yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun. Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì; wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn, wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.