Isa 43:6-7
Isa 43:6-7 Yoruba Bible (YCE)
N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀.’ N óo sọ fún ìhà gúsù pé, ‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’ Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè, sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé, gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè, àwọn tí mo dá fún ògo mi, àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”
Isa 43:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá. Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogo mi, mo ti mọ ọ, ani, mo ti ṣe e pé.
Isa 43:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé— ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”