Isa 46:10-11
Isa 46:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti nsọ opin lati ipilẹṣẹ wá, ati nkan ti kò ti iṣe lati igbãni wá, wipe, Imọ mi yio duro, emi o si ṣe gbogbo ifẹ mi. Ẹniti npe idì lati ilà-õrun wá: ọkunrin na ti o mu ìmọ mi ṣẹ lati ilẹ jijìn wá: lõtọ, emi ti sọ ọ, emi o si mu u ṣẹ; emi ti pinnu rẹ̀, emi o si ṣe e pẹlu.
Isa 46:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ Mo pe idì láti ìlà oòrùn, mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá. Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ, mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é.
Isa 46:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá. Mo wí pé: Ète mi yóò dúró, àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí. Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá; láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ. Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ; èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.