Isa 48:17-18
Isa 48:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ. Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun.
Isa 48:17-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani, tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà. “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi, alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò, òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.
Isa 48:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí OLúWA wí Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.