Isa 49:13-16
Isa 49:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kọrin, ẹnyin ọrun; ki o si yọ̀, iwọ aiye; bú jade ninu orin, ẹnyin oke-nla: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, yio si ṣãnu fun awọn olupọnju rẹ̀. Ṣugbọn Sioni wipe, Oluwa ti kọ̀ mi silẹ; Oluwa mi si ti gbagbe mi. Obinrin ha lè gbagbe ọmọ ọmú rẹ̀ bi, ti kì yio fi ṣe iyọ́nu si ọmọ inu rẹ̀? lõtọ, nwọn le gbagbe, ṣugbọn emi kì yio gbagbe rẹ. Kiye si i, emi ti kọ ọ si atẹlẹwọ mi: awọn odi rẹ mbẹ niwaju mi nigbagbogbo.
Isa 49:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Kí ọ̀run kọrin ayọ̀, kí ayé kún fún ayọ̀, ẹ̀yin òkè, ẹ máa kọrin, nítorí, OLUWA ti tu àwọn eniyan rẹ̀ ninu, yóo ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀ tí ìyà ń jẹ. Sioni ń wí pé, “OLUWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Oluwa mi ti gbàgbé mi.” OLUWA dáhùn pé, “Ǹjẹ́ abiyamọ le gbàgbé ọmọ tí ń fún lọ́mú? Ṣé ó le má ṣàánú ọmọ bíbí inú rẹ̀? Bí àwọn wọnyi tilẹ̀ gbàgbé. Èmi kò ní gbàgbé rẹ. Wò ó! Mo ti fi gègé fín orúkọ rẹ sí àtẹ́lẹwọ́ mi, àwọn odi rẹ sì ńbẹ níwájú mi nígbà gbogbo.
Isa 49:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí OLúWA tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú. Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “OLúWA ti kọ̀ mí sílẹ̀, Olúwa ti gbàgbé è mi.” “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé Èmi kì yóò gbàgbé rẹ! Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.