Isa 52:14-15
Isa 52:14-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi ẹnu rẹ ti yà ọ̀pọlọpọ enia, a bà oju rẹ̀ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati irisi rẹ̀ ju ti ọmọ enia lọ. Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.
Isa 52:14-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnu ti ya ọpọlọpọ eniyan nítorí rẹ̀. Wọ́n bà á lójú jẹ́ yánnayànna, tóbẹ́ẹ̀ tí ìrísí rẹ̀ kò fi jọ ti eniyan mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni yóo di ohun ìyanu fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, kẹ́kẹ́ yóo pamọ́ àwọn ọba wọn lẹ́nu, nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn óo rí ohun tí wọn kò gbọ́ rí nípa rẹ̀, òye ohun tí wọn kò mọ̀ rí yóo yé wọn.
Isa 52:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un— ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká, àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀. Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i, àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.