Isa 55:10-11
Isa 55:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gẹgẹ bi òjo ati ojo-didì ti iti ọrun wá ilẹ, ti kì isi tun pada sọhun, ṣugbọn ti o nrin ilẹ, ti o si nmu nkan hù jade ki o si rudi, ki o le fi irú fun awọn afúnrúgbìn, ati onjẹ fun ọjẹun: Bẹ̃ni ọ̀rọ mi ti o ti ẹnu mi jade yio ri: kì yio pada sọdọ mi lofo, ṣugbọn yio ṣe eyiti o wù mi, yio si ma ṣe rere ninu ohun ti mo rán a.
Isa 55:10-11 Yoruba Bible (YCE)
“Bí òjò ati yìnyín, tí ń rọ̀ láti ojú ọ̀run, tí wọn kì í pada sibẹ mọ́, ṣugbọn tí wọn ń bomi rin ilẹ̀, tí ń mú kí nǹkan hù jáde; kí àgbẹ̀ lè rí èso gbìn, kí eniyan sì rí oúnjẹ jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu mi yóo rí, kò ní pada sí ọ̀dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣugbọn yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ kí ó ṣe, yóo sì ṣe é ní àṣeyọrí.
Isa 55:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín ti wálẹ̀ láti ọ̀run tí kì í sì padà sí ibẹ̀ láì bomirin ilẹ̀ kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi, tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn àti àkàrà fún ọ̀jẹun, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá; kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo, ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́, yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.