Isa 58:6-7
Isa 58:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.
Isa 58:6-7 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣebí irú ààwẹ̀ tí mo yàn ni pé: kí á tú ìdè ìwà burúkú, kí á yọ irin tí a fi di igi àjàgà; kí á dá àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́, kí á já gbogbo àjàgà? Àní kí ẹ fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, kí ẹ mú àwọn òtòṣì aláìnílé wá sinu ilé yín, bí ẹ bá rí ẹnikẹ́ni ní ìhòòhò, kí ẹ fi aṣọ bò ó, kí ẹ má sì fojú pamọ́ fún ẹni tí ó jẹ́ ẹbí yín.
Isa 58:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí: láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo àti láti tú gbogbo okùn àjàgà, láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀ àti láti fọ́ gbogbo àjàgà? Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri. Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó, àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?