Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Jak 1:1-3YBCV(Bibeli Mimọ)
JAKỌBU, iranṣẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa, si awọn ẹ̀ya mejila ti o túka kiri, alafia. Ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba bọ́ sinu onirũru idanwò, ẹ kà gbogbo rẹ̀ si ayọ; Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru.
Pín
Jak 1YBCVJak 1:1-3BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jakọbu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa, Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káàkiri, orílẹ̀-èdè: Àlàáfíà. Ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdánwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣiṣẹ́ sùúrù.
Pín
Jak 1BMYOJak 1:1-3YCE(Yoruba Bible)
Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín! Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín. Kí ẹ mọ̀ pé ìdánwò igbagbọ yín ń mú kí ẹ ní ìfaradà.
Pín
Jak 1YCE