A. Oni 11:30-31
A. Oni 11:30-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jefta sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLúWA pé, “Bí ìwọ bá fi àwọn ará Ammoni lé mi lọ́wọ́, Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ó bá jáde láti ẹnu-ọ̀nà ilé mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ammoni ní àlàáfíà, yóò jẹ́ ti OLúWA, èmi yóò sì fi rú ẹbọ bí ọrẹ ẹbọ sísun.”
A. Oni 11:30-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ, Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun.
A. Oni 11:30-31 Yoruba Bible (YCE)
Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni, nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.”