A. Oni 7:3
A. Oni 7:3 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, kéde fún gbogbo wọn pé, kí ẹnikẹ́ni tí ẹ̀rù bá ń bà pada sí ilé.” Gideoni bá dán wọn wò lóòótọ́, ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) ọkunrin ninu wọn sì pada sí ilé. Àwọn tí wọ́n kù jẹ́ ẹgbaarun (10,000).
Pín
Kà A. Oni 7A. Oni 7:3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun.
Pín
Kà A. Oni 7A. Oni 7:3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
sì kéde sí àwọn ènìyàn nísinsin yìí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbọ̀n, tí ó sì ń bẹ̀rù lè padà sẹ́yìn, kí ó sì kúrò lórí òkè Gileadi.’ ” Báyìí ni Gideoni ṣe ya àwọn ènìyàn náà. Ẹgbẹ̀rúnméjìlélógún ọkùnrin sì padà sẹ́yìn àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró.
Pín
Kà A. Oni 7