Jer 1:5-10
Jer 1:5-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède. Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi. Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ. Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi. Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu. Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn.
Jer 1:5-10 Yoruba Bible (YCE)
“Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Mo bá dáhùn pé, “Háà! OLUWA Ọlọrun! Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.” Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní, “Má pe ara rẹ ní ọmọde, nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ. Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ. Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.” OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu. Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí, láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀, láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú, láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”
Jer 1:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè. Mo sọ pé, “Háà! OLúWA Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” OLúWA sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” OLúWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́. OLúWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.