Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Jer 19:4YBCV(Bibeli Mimọ)

Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi

Jer 19:4BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.

Jer 19:4YCE(Yoruba Bible)

Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí.