Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Jer 22:15-16YBCV(Bibeli Mimọ)

Iwọ o ha jọba, nitori iwọ fi igi kedari dije? baba rẹ kò ha jẹ, kò ha mu? o si ṣe idajọ ati ododo, nitorina o dara fun u. O dajọ ọ̀ran talaka ati alaini; o dara fun u: bi ãti mọ̀ mi kọ́ eyi? li Oluwa wi.

Jer 22:15-16BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Ìwọ ó ha jẹ ọba kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari? Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu? Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo, nítorí náà ó dára fún un. Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní, ohun gbogbo sì dára fún un. Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?” ni OLúWA wí.

Jer 22:15-16YCE(Yoruba Bible)

Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba? Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni, tabi kò rí mu? Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, ṣebí ó sì dára fún un. Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní, ohun gbogbo sì ń lọ dáradára. Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA? OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.