Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Jer 22:3YBCV(Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Mu idajọ ati ododo ṣẹ, ki o si gbà ẹniti a lọ lọwọ gbà kuro lọwọ aninilara, ki o máṣe fi agbara ati ìka lò alejo, alainibaba ati opó, bẹ̃ni ki o máṣe ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ nihinyi.
Pín
Jer 22YBCVJer 22:3BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLúWA wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
Pín
Jer 22BMYOJer 22:3YCE(Yoruba Bible)
Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí.
Pín
Jer 22YCE