Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Jer 28:15-16YBCV(Bibeli Mimọ)

Nigbana ni Jeremiah, woli, wi fun Hananiah, woli, pe, Gbọ́ nisisiyi, Hananiah; Oluwa kò rán ọ; ṣugbọn iwọ jẹ ki enia yi ki o gbẹkẹle eke. Nitorina bayi li Oluwa wi; Sa wo o, emi o ta ọ nù kuro loju aiye: li ọdun yi ni iwọ o kú, nitori iwọ ti sọ̀rọ iṣọtẹ si Oluwa.

Jer 28:15-16BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Wòlíì Jeremiah sọ fún wòlíì Hananiah pé, “Gbọ́ ọ, Hananiah! OLúWA kò rán ọ, síbẹ̀, ìwọ jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yìí gba irọ́ gbọ́. Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLúWA wí: ‘Mo ṣetán láti mú ọ kúrò nínú ayé, ní ọdún yìí ni ìwọ yóò kú nítorí o ti wàásù ọ̀tẹ̀ sí OLúWA.’ ”

Jer 28:15-16YCE(Yoruba Bible)

Jeremaya wolii bá sọ fún Hananaya pé, “Tẹ́tí sílẹ̀, Hananaya, OLUWA kò rán ọ níṣẹ́, o sì ń jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gbẹ́kẹ̀lé irọ́. Nítorí náà, OLUWA ní: òun óo mú ọ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní ọdún yìí gan-an ni o óo sì kú, nítorí pé o ti sọ ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”