Jer 3:13-14
Jer 3:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi. Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo; emi o si mu nyin, ọkan ninu ilu kan, ati meji ninu idile kan; emi o si mu nyin wá si Sioni.
Jer 3:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi, ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa, lábẹ́ gbogbo igi tútù; o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.
Jer 3:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ” ni OLúWA wí. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni OLúWA wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.