Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Jer 30:17YBCV(Bibeli Mimọ)

Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀!

Jer 30:17BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni OLúWA wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri, Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’

Jer 30:17YCE(Yoruba Bible)

N óo fun yín ní ìlera, n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù, Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”