Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Jer 35:15YBCV(Bibeli Mimọ)
Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.
Jer 35:15BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.
Jer 35:15YCE(Yoruba Bible)
Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.