Joh 13:12-15
Joh 13:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó ti fọ ẹsẹ̀ wọn tán, ó wọ agbádá rẹ̀, ó bá tún jókòó. Ó wá bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe si yín? Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Bí èmi Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ máa fọ ẹsẹ̀ ẹnìkejì yín. Àpẹẹrẹ ni mo fi fun yín pé, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe.
Joh 13:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina lẹhin ti o wẹ̀ ẹsẹ wọn tan, ti o si ti mu agbáda rẹ̀, ti o tún joko, o wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ohun ti mo ṣe si nyin? Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ. Njẹ bi emi ti iṣe Oluwa ati Olukọni nyin ba wẹ̀ ẹsẹ nyin, o tọ́ ki ẹnyin pẹlu si mã wẹ̀ ẹsẹ ara nyin. Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin.
Joh 13:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí? Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín.