Joh 21:15-19
Joh 21:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi. O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi. O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, nigbati iwọ wà li ọdọmọde, iwọ a ma di ara rẹ li àmurè, iwọ a si ma rìn lọ si ibiti iwọ ba fẹ: ṣugbọn nigbati iwọ ba di arugbo, iwọ o nà ọwọ́ rẹ jade, ẹlomiran yio si di ọ li amure, yio si mu ọ lọ si ibiti iwọ kò fẹ. O wi eyi, o fi nṣapẹrẹ irú ikú ti yio fi yìn Ọlọrun logo. Lẹhin igbati o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.
Joh 21:15-19 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?” Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.” Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.” Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi. Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́, ò ń di ara rẹ ni àmùrè gírí, ò ń lọ sí ibi tí o bá fẹ́. Ṣugbọn nígbà tí o bá di arúgbó, ìwọ yóo na ọwọ́ rẹ, ẹlòmíràn yóo wọ aṣọ fún ọ, yóo fà ọ́ lọ sí ibi tí o kò fẹ́ lọ.” (Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”
Joh 21:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.” Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?” Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.” Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”