Job 33:15-18
Job 33:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru, nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn, Ọlọrun a máa ṣí wọn létí, a máa kìlọ̀ fún wọn, a sì máa dẹ́rùbà wọ́n, kí ó lè dá wọn lẹ́kun ìṣe wọn, kí ó lè gba ìgbéraga lọ́wọ́ wọn; kí ó lè yọ ọkàn eniyan kúrò ninu ọ̀fìn ìparun, kí ó má baà kú ikú idà.
Job 33:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun. Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn. Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia. O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà.
Job 33:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí orun èjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ibùsùn, Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí, Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn; Ó sì fa ọkàn rẹ̀ padà kúrò nínú isà òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣègbé lọ́wọ́ idà.