Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Joel 1:14YBCV(Bibeli Mimọ)

Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa

Joel 1:14BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLúWA Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe OLúWA.

Joel 1:14YCE(Yoruba Bible)

Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì pe àpèjọ. Ẹ pe àwọn àgbààgbà, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì kígbe pe OLUWA.