Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Joel 2:13YBCV(Bibeli Mimọ)

Ẹ si fà aiyà nyin ya, kì isi ṣe aṣọ nyin, ẹ si yipadà si Oluwa Ọlọrun nyin, nitoriti o pọ̀ li ore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ̀, o si ronupiwada ati ṣe buburu.

Joel 2:13BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ sì fa ọkàn yín ya, kì í sì í ṣe aṣọ yín, ẹ sì yípadà sí OLúWA Ọlọ́run yín, nítorí tí o pọ̀ ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì kún fun àánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ṣeun púpọ̀, ó sì ronúpìwàdà láti ṣe búburú.

Joel 2:13YCE(Yoruba Bible)

Ìrònúpìwàdà tòótọ́ ni mò ń fẹ́, kì í ṣe pé kí ẹ fa aṣọ yín ya nìkan.” Ẹ yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, nítorí olóore-ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni. Kì í yára bínú, Ó kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, a sì máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan.