Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Joel 3:15-16YBCV(Bibeli Mimọ)
Õrùn ati oṣupa yio ṣu òkunkun, ati awọn irawọ̀ yio fà titàn wọn sẹhin. Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.
Pín
Joel 3YBCVJoel 3:15-16BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́. OLúWA yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n OLúWA yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.
Pín
Joel 3BMYOJoel 3:15-16YCE(Yoruba Bible)
Oòrùn ati òṣùpá ti ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ kò sì tan ìmọ́lẹ̀ mọ́. OLUWA kígbe láti Sioni, ó sọ̀rọ̀ láti Jerusalẹmu; ọ̀run ati ayé mì tìtì, ṣugbọn OLUWA ni ààbò fún àwọn eniyan rẹ̀, òun ni ibi ààbò fún Israẹli.
Pín
Joel 3YCE