Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Joṣ 14:12YBCV(Bibeli Mimọ)

Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi.

Joṣ 14:12BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí OLúWA ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí OLúWA ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”

Joṣ 14:12YCE(Yoruba Bible)

Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.”