Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Joṣ 24:14YBCV(Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA.
Pín
Joṣ 24YBCVJoṣ 24:14BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù OLúWA, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin OLúWA.
Pín
Joṣ 24BMYOJoṣ 24:14YCE(Yoruba Bible)
“Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA.
Pín
Joṣ 24YCE