Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Ẹk. Jer 1:1YBCV(Bibeli Mimọ)
BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú!
Ẹk. Jer 1:1BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní ipò opó, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú ni ó padà di ẹrú.
Ẹk. Jer 1:1YCE(Yoruba Bible)
Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro, tí ó wá dàbí opó! Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀! Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin láàrin àwọn ìlú yòókù. Ó ti wá di ẹni àmúsìn.
Pín
Ẹk. Jer 1YCE