Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Ẹk. Jer 1:2YBCV(Bibeli Mimọ)
On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀.
Ẹk. Jer 1:2BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
Ẹk. Jer 1:2YCE(Yoruba Bible)
Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru, omijé ń dà lójú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀.
Pín
Ẹk. Jer 1YCE