Lef 20:26 - Compare All Versions

Lef 20:26 YBCV (Bibeli Mimọ)

Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi.

Lef 20:26 YCE (Yoruba Bible)

Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi.

Lef 20:26 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé, Èmi OLúWA fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.