Luk 1:39-45
Luk 1:39-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkókò náà ni Maria sì dìde, ó lọ kánkán sí ilẹ̀ òkè, sí ìlú kan ní Judea; Ó sì wọ ilé Sekariah lọ ó sì kí Elisabeti. Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí mímọ́; Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkún fún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí. Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀. Alábùkún fún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”
Luk 1:39-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda; O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti. O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́: O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ. Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá? Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀. Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ.
Luk 1:39-45 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Maria múra pẹlu ìwàǹwára, ó lọ sí ìlú Judia kan tí ó wà ní agbègbè orí òkè. Ó wọ inú ilé Sakaraya, ó bá kí Elisabẹti. Bí Elisabẹti ti gbọ́ ohùn Maria, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabẹti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó kígbe sókè, ó ní, “Ibukun Ọlọrun wà lórí rẹ pupọ láàrin àwọn obinrin. Ibukun Ọlọrun sì wà lórí ọmọ inú rẹ. Mo ṣe ṣe oríire tó báyìí, tí ìyá Oluwa mi fi wá sọ́dọ̀ mi? Nítorí bí mo ti gbọ́ ohùn rẹ nígbà tí o kí mi, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ inú mi sọ nítorí ó láyọ̀. Ayọ̀ ń bẹ fún ọ nítorí o gba ohun tí Oluwa ti sọ gbọ́, pé yóo ṣẹ.”