Luk 2:16-19
Luk 2:16-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀.
Luk 2:16-19 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n bá yára lọ. Wọ́n wá Maria kàn ati Josẹfu ati ọmọ-ọwọ́ náà tí a tẹ́ sí ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sọ ohun gbogbo tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ náà. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́-aguntan náà sọ fún wọn. Ṣugbọn Maria ń ṣe akiyesi gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó ń dà wọ́n rò ní ọkàn rẹ̀.
Luk 2:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Maria àti Josẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. Ṣùgbọ́n Maria pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.