Luk 2:25-32
Luk 2:25-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e. A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa. O si ti ipa Ẹmí wá sinu tẹmpili: nigbati awọn obi rẹ̀ si gbé ọmọ na Jesu wá, lati ṣe fun u bi iṣe ofin. Nigbana li o gbé e li apa rẹ̀, o fi ibukun fun Ọlọrun, o ni, Oluwa, nigbayi li o to jọwọ ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ lọ li alafia, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ: Nitoriti oju mi ti ri igbala rẹ na, Ti iwọ ti pèse silẹ niwaju enia gbogbo; Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.
Luk 2:25-32 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan wà ní Jerusalẹmu tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simeoni. Ó jẹ́ olódodo eniyan ati olùfọkànsìn, ó ń retí àkókò tí Ọlọrun yóo tu Israẹli ninu. Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹlu rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ti fihàn án pé kò ní tíì kú tí yóo fi rí Mesaya tí Oluwa ti ṣe ìlérí. Ẹ̀mí wá darí rẹ̀ sí Tẹmpili ní àkókò tí àwọn òbí ọmọ náà gbé e wá, láti ṣe gbogbo ètò tí ó yẹ gẹ́gẹ́ bí òfin. Ni Simeoni bá gbé ọmọ náà lọ́wọ́, ó yin Ọlọrun lógo, ó ní, “Nisinsinyii, Oluwa, dá ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ sílẹ̀ ní alaafia, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nítorí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ, tí o ti pèsè níwájú gbogbo eniyan; ìmọ́lẹ̀ láti fi ọ̀nà han àwọn kèfèrí ati ògo fún Israẹli, eniyan rẹ.”
Luk 2:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní: “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ, ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ: Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná, Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo; ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”