Luk 20:46-47
Luk 20:46-47 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè. Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”
Luk 20:46-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.
Luk 20:46-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”