Luk 3:4-6
Luk 3:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi a ti kọ ọ ninu iwe ọ̀rọ woli Isaiah pe, Ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ mu ipa-ọna rẹ̀ tọ́. Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna; Gbogbo enia ni yio si ri igbala Ọlọrun.
Luk 3:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Èyí rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé ọ̀rọ̀ wolii Aisaya pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní aṣálẹ̀ pé, ‘Ẹ la ọ̀nà fún Oluwa, ẹ ṣe ojú ọ̀nà tí ó tọ́ fún un láti rìn! Gbogbo ọ̀gbun ni yóo jẹ́ dídí gbogbo òkè gíga ati òkè kéékèèké ni yóo jẹ́ rírẹ̀ sílẹ̀. A óo tọ́ ibi tí ó bá ṣe kọ́rọ-kọ̀rọ, a óo sì sọ ọ̀nà tí kò bá dán tẹ́lẹ̀ di dídán Gbogbo eniyan ni yóo rí ìgbàlà Ọlọrun.’ ”
Luk 3:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah pé, “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Gbogbo ọ̀gbun ni a yóò kún, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ́ pẹẹrẹ; Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́, àti ọ̀nà gbọ́ngungbọ̀ngun ni a o sọ di dídán. Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”