Luk 6:12-16
Luk 6:12-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun. Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli; Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu, Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote, Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.
Luk 6:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli: Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀, Jakọbu, Johanu, Filipi, Bartolomeu, Matiu, Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni tí a ń pè ní Sealoti, Judea arákùnrin Jakọbu, àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀.
Luk 6:12-16 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó yan àwọn mejila ninu wọn, tí ó pè ní aposteli. Àwọn ni Simoni tí ó sọ ní Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filipi ati Batolomiu, Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu ati Simoni tí ó tún ń jẹ́ Seloti, Judasi ọmọ Jakọbu ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó di ọ̀dàlẹ̀.