Luk 8:47-48
Luk 8:47-48 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.”
Luk 8:47-48 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati obinrin na si mọ̀ pe on ko farasin, o warìri, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ fun u li oju awọn enia gbogbo nitori ohun ti o ṣe, ti on fi fi ọwọ́ tọ́ ọ, ati bi a ti mu on larada lojukanna. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, tújuka: igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia.
Luk 8:47-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; máa lọ ní Àlàáfíà!”