Mal 4:5-6 - Compare All Versions

Mal 4:5-6 YBCV (Bibeli Mimọ)

Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de: Yio si pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkàn awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o má ba wá fi aiye gégun.

Mal 4:5-6 YCE (Yoruba Bible)

“Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé. Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.”

Mal 4:5-6 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Wò ó, èmi yóò rán wòlíì Elijah sí i yín, ki ọjọ́ ńlá, ọjọ́ ẹ̀rù OLúWA to dé. Òun yóò sì pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ọkàn àwọn ọmọ sì ti àwọn baba wọn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò wá, èmi yóò sì fi ilẹ̀ náà gégùn.”