Mat 1:18-25
Mat 1:18-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ibí Jesu Kristi ti ri niyi: li akokò ti a fẹ Maria iya rẹ̀ fun Josefu, ki nwọn to pade, a ri i, o lóyun lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá. Josefu ọkọ rẹ̀, ti iṣe olõtọ enia, ko si fẹ dojutì i ni gbangba, o fẹ ikọ̀ ọ silẹ ni ìkọkọ. Ṣugbọn nigbati o nrò nkan wọnyi, wò o, angẹli Oluwa yọ si i li oju alá, o wipe, Josefu, iwọ ọmọ Dafidi, má fòiya lati mu Maria aya rẹ si ọdọ; nitori eyi ti o yún ninu rẹ̀, lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ ni. Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn. Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa. Nigbati Josefu dide ninu orun rẹ̀, o ṣe bi angẹli Oluwa ti wi fun u, o si mu aya rẹ̀ si ọdọ: On ko si mọ̀ ọ titi o fi bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin: o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU.
Mat 1:18-25 Yoruba Bible (YCE)
Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Eniyan rere ni Josẹfu ọkọ rẹ̀, kò fẹ́ dójú tì í, ó fẹ́ rọra kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́. Bí ó ti ń ronú bí yóo ti gbé ọ̀rọ̀ náà gbà, angẹli Oluwa kan fara hàn án lójú àlá. Ó sọ fún un pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má bẹ̀rù láti mú Maria aya rẹ sọ́dọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni oyún tí ó ní. Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé, “Wundia kan yóo lóyún, yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”) Nígbà tí Josẹfu jí láti ojú oorun, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Oluwa náà ti pàṣẹ fún un. Ó mú iyawo rẹ̀ sọ́dọ̀. Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.
Mat 1:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.” Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.