Mat 1:21-23
Mat 1:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si bí ọmọkunrin kan, Jesu ni iwọ o pè orukọ rẹ̀: nitori on ni yio gbà awọn enia rẹ̀ là kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn. Gbogbo eyi si ṣẹ, ki eyi ti a ti sọ lati ọdọ Oluwa wá li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.
Mat 1:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii nì lè ṣẹ pé, “Wundia kan yóo lóyún, yóo bí ọmọkunrin kan; wọn yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.” (Ìtumọ̀, “Imanuẹli” ni “Ọlọrun wà pẹlu wa.”)
Mat 1:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: “Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”