Mat 19:4-5
Mat 19:4-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo, O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan.
Pín
Kà Mat 19Mat 19:4-5 Yoruba Bible (YCE)
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀, takọ-tabo ni ó dá wọn, tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’
Pín
Kà Mat 19Mat 19:4-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’
Pín
Kà Mat 19