Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Mat 2:9YBCV(Bibeli Mimọ)

Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà.

Mat 2:9BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títí tí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.

Mat 2:9YCE(Yoruba Bible)

Nígbà tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n lọ. Bí wọ́n ti ń lọ, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí ní ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí lọ níwájú wọn títí ó fi dúró ní ọ̀gangan ibi tí ọmọ náà wà.