Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Mat 26:57-67YBCV(Bibeli Mimọ)
Awọn ti o si mu Jesu, fà a lọ si ile Kaiafa, olori alufa, nibiti awọn akọwe ati awọn agbàgba gbé pejọ si. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ́ lẹhin li òkere titi fi de agbala olori alufa, o bọ́ si ile, o si bá awọn ọmọ-ọdọ na joko lati ri opin rẹ̀. Nigbana li olori alufa, ati awọn alàgba, ati gbogbo ajọ igbimọ nwá ẹlẹri eke si Jesu lati pa a; Ṣugbọn nwọn ko ri ohun kan: otitọ li ọ̀pọ ẹlẹri eke wá, ṣugbọn nwọn kò ri ohun kan. Nikẹhin li awọn ẹlẹri eke meji wá; Nwọn wipe, ọkunrin yi wipe, Emi le wó tẹmpili Ọlọrun, emi o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta. Olori alufa si dide, o si wi fun u pe, Iwọ ko dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? Ṣugbọn Jesu dakẹ. Olori alufa dahùn o si wi fun u pe, Mo fi Ọlọrun alãye bẹ̀ ọ pé, ki iwọ ki o sọ fun wa bi iwọ ba ṣe Kristi Ọmọ Ọlọrun. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi i: ṣugbọn mo wi fun nyin, Lẹhin eyi li ẹnyin o ri Ọmọ-enia ti yio joko li ọwọ́ ọtún agbara, ti yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, O sọ ọrọ-odi; ẹlẹri kili a si nwá? wo o, ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na nisisiyi. Ẹnyin ti rò o si? Nwọn dahùn, wipe, O jẹbi ikú. Nigbana ni nwọn tutọ́ si i loju, nwọn kàn a lẹṣẹ́; awọn ẹlomiran fi atẹ́lọwọ́ wọn gbá a loju
Mat 26:57-67BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan. Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde. Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ” Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ń kọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́. Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè, kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.” Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.” Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” Ki ni ẹ ti rò èyí sí. Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!” Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.
Mat 26:57-67YCE(Yoruba Bible)
Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí. Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á. Ṣugbọn wọn kò rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọpọ ni àwọn ẹlẹ́rìí-èké tí wọ́n yọjú. Ní ìgbẹ̀yìn àwọn meji kan wá. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí sọ pé, ‘Mo lè wó Tẹmpili Ọlọrun yìí, kí n sì tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.’ ” Olórí Alufaa bá dìde, ó ní, “O kò fèsì rárá? Àbí o kò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ pé o wí?” Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.” Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.” Olórí Alufaa bá fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “O sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àfojúdi tí ó sọ sí Ọlọrun nisinsinyii. Kí ni ẹ rò?” Wọ́n dáhùn pé, “Ikú ni ó tọ́ sí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lójú, wọ́n ń sọ ọ́ lẹ́ṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń gbá a létí.