Mat 5:11-12
Mat 5:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi. Ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o si fò fun ayọ̀: nitori ère nyin pọ̀ li ọrun: bẹ̃ni nwọn sá ṣe inunibini si awọn wolĩ ti o ti mbẹ ṣaju nyin.
Mat 5:11-12 Yoruba Bible (YCE)
“Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi. Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín.
Mat 5:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Alábùkún fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, tiwọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.