Mat 6:19-21
Mat 6:19-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale: Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale. Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.
Mat 6:19-21 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ má ṣe kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ayé, níbi tí kòkòrò lè bà á jẹ́, tí ó sì lè dógùn-ún. Àwọn olè tún lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ. Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀. Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà.
Mat 6:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.