Ṣe àfiwé gbogbo èyà
Mat 6:20-22YBCV(Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale. Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu. Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ.
Mat 6:20-22BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú. “Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀.
Mat 6:20-22YCE(Yoruba Bible)
Ṣugbọn ẹ kó ìṣúra jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí kòkòrò kò lè bà á jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè dógùn-ún, àwọn olè kò sì lè wá a kàn kí wọ́n jí i lọ níbẹ̀. Nítorí níbi tí ìṣúra rẹ bá wà, níbẹ̀ náà ni ọkàn rẹ yóo wà. “Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara. Bí ojú rẹ bá ríran kedere, gbogbo ara rẹ yóo ní ìmọ́lẹ̀.