Àmì Ìdánimọ̀ Ohun-èlò Bíbélì
Ṣe Àwárí

Ṣe àfiwé gbogbo èyà

Mik 2:13YBCV(Bibeli Mimọ)

Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.

Mik 2:13BMYO(Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn; wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ. Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, OLúWA ni yóò sì ṣe olórí wọn.”

Mik 2:13YCE(Yoruba Bible)

Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.