Mik 4:2 - Compare All Versions
Mik 4:2 YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.
Pín
Mik 4 YBCVMik 4:2 YCE (Yoruba Bible)
Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ sórí òkè OLUWA, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí á sì lè máa tọ̀ ọ́.” Nítorí pé láti Sioni ni òfin yóo ti máa jáde, ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì máa jáde láti Jerusalẹmu.
Pín
Mik 4 YCEMik 4:2 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu.
Pín
Mik 4 BMYO