Mik 4:3 - Compare All Versions
Mik 4:3 YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.
Pín
Mik 4 YBCVMik 4:3 YCE (Yoruba Bible)
Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ati láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lágbára ní ọ̀nà jíjìn réré; wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.
Pín
Mik 4 YCEMik 4:3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.
Pín
Mik 4 BMYO